Enimere Àkànbí
Ìjọba àpapọ̀ oríléèdè Nàìjíríà ti kéde ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ati ọjọ́bọ̀, ọjọ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kàrún-un ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ láti fi ṣe ayẹyẹ Eid-el-kabir, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí ọdún iléyá.
Alákòóso, Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́, Ọ̀gbẹ́ni Olúbùnmi Túnjí-Òjó, ló ṣe ìkéde yìí nínú àtẹ̀jáde tó fi rán akọ̀wé àgbà iléeṣẹ́ ọ̀hún, Arábìnrin Magdalene Àjàní.
Nínú àtẹ̀jáde náà ni Ọ̀gbẹ́ni Túnjí-Òjó, ti tọ́ka ìkéde ọ̀hún gẹ́gẹ́ ohun tó ṣe àfihàn ìbọ̀wọ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ní fún ẹ̀sìn Islam, àwọn Mùsùlùmí lórílẹ̀èdè Nàìjíríà àti káàkiri àgbáyé tó ń gbaradì fún ọdún iléyá.
Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Túnjí-Òjó, ń kí àwọn Mùsùlùmí òdodo kú ọdún iléyá, ó gbà wọ́n níyànjú láti fi àkókò náà fi gbàdúrà sí Ọlọ́run Ọba fún àlàáfíà, ìṣọ̀kan àti àṣeyọrí oríléèdè yìí.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply