SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Tinúbú Yan Ẹni Ọdún Mọ́kàndínlógójì Gẹ́gẹ́ Bíi Ọ̀gá Àgbà Àjọ JAMB

images

Enimere Àkànbí
Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà, Bọlá Tinúbú ti yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Sẹ́gun Àìná, gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé àgbà àjọ tó ń ṣe ètò ìdánwò aláṣe wọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, JAMB.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Àìná, ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì ni Ààrẹ yàn láti rọ́pò Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq Olóyèdé, tí àkókò rẹ̀ yóò tẹnu bodò lọ́jọ́ kọ̀kànlélọ́gbọ̀n oṣù keje, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

Nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Báyọ̀ Ọnànúgà, ni wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé Àìná jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kọ́ nípa ìmọ̀-ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, tó ń bẹ ní ìlú Ilé-Ifẹ̀, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, pẹ̀lú ìmọ̀ kíkún nípa àgbékalẹ̀ ètò ìdánwò àti àtúntò àwọn ibùdó ìmọ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Àìná, tí yóò pé ẹni ogójì ọdún nínú oṣù keje ọdún yìí, jẹ́ ẹni tó ní ìmọ̀ tó gbòòrò nínú àgbékalẹ̀ ìdánwò, ní ìlànà tó péye.

Ó jẹ́ ẹni tó kọ́ ẹ̀kọ́ gba ìmọ̀ kíkún nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Kent àti àwọn òye ìmọ̀ ẹ̀kọ́ míì.

Bákan náà ni àtẹ̀jáde ọ̀hún fi kún-un pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Àìnà, ní ìrírí ọdún mẹ́ẹ̀dógún nínú gbígba ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba ìpínlẹ̀ nímọ̀ràn lórí àyípadà ìmọ̀-ẹ̀rọ, àtúntò àti àgbékalẹ̀ ètò àwọn ibùdó ìkẹ̀kọ̀ọ́.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *