SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

GÓMÌNÀ MÁKINDÉ LÓUN YÓÒ TẸ́TÍ SÍ ÌBÉÈRÈ ÀWỌN AJÍNIGBÉ, KÍNNÍ ÀÀRẸ TINÚBÚ, ẸGBẸ́ CAN SỌ

img 20260519 wa0006

Enimere Àkànbí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìṣàkóso òun kò ní jọ̀gọ̀ sílẹ̀ fún ìpániláyà tàbí ìdúnkokò mọ́ ni, gẹ́gẹ́ bíi irú èyí tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn agbébọn kan jí àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ oríire.

Gómìnà Mákindé, sọ pé ṣùgbọ́n ṣá ìjọba òun ti ṣe tán láti tẹ́tí sí nǹkan tí àwọn ajínigbé ọ̀hún ń fẹ́, ká ní pé ìgbésẹ̀ yìí ni yóò ṣe atọ́nà bí àwọn tó ń bẹ ní àkàta àwọn ajínigbé yóò fi tètè rí òmìnira gbà ní àlàáfíà.

Gómìnà sọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ nígbà tó ń bun àwọn oníròyìn gbọ̀ọ́ nípa ipò tí nǹkan dé dúró, lórí ìkọlù àti ìjínigbé ọ̀hún tó wáyé lọ́jọ́ ẹtì tó kọjá.

Gómìnà Mákindé, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àpapọ̀ èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n ni wọ́n jígbé lákòókò ìkọlù náà, tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méje láti ilé ẹ̀kọ́ girama Community Secondary School, àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ méjìdínlógún àti olùkọ́ méje ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́ẹ̀rẹ́ tó jẹ́ ti aládàáni, first Baptist primary and nursery school, pẹ̀lú àfikún pé àwọn ẹ̀ṣọ́ alaabo ń ṣe akitiyan lọ́wọ́ láti gbà á wón sílẹ̀.

Gómìnà gba àwọn aráàlú níyànjú láti ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ikọ̀ alaabo, láti ara fífi ìfitónilétí tí wọ́n bá ní láti ara ìfimúfínlẹ̀ wọn tó àwọn ẹ̀ṣọ́ alaabo létí, pẹ̀lú àfikún pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwùjọ jẹ́ nǹkan gbòógì nínú ìgbésẹ̀ láti rí ẹ̀yìn ètò ààbò tí kò péye.

Gómìnà Mákindé, sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn oníròyìn àti àwùjọ láti yàgò fún ṣíṣe ìtànkálẹ̀ àwọn ibi tí nǹkan dé dúró nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ́nà tó le mí a fa ìbẹ̀rùbojo, nítorí pé ó ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí àwọn èèyàn.

Nínú ìròyìn tó fi ara pẹ́ ẹ, Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà, Bọlá Tinúbú, bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ajínigbé ṣe gba ẹ̀mí ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilẹ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n jígbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Oríire nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, tó sì fi ògún rẹ̀ gbárí pé akitiyan àwọn ikọ̀ alaabo yóò bí òmìnira àwọn yòókù tó ń bẹ ní ìgbèkùn.

Ààrẹ Tinúbú, nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Báyọ̀ Ọnànúgà, ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi èyí tí kò bá ìwà ọmọnìyàn dọ́gba.

Ó bá ẹbí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kẹ́dùn, pẹ̀lú àfikún pé àwọn tí rán àwọn ikọ̀ alaabo láti tọ ipasẹ̀ àwọn oníṣẹ́ ibi náà lọ, kí wọ́n sì gba àwọn tí ó ń bẹ lákàtà wọn sílẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà CAN, ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ajínigbé ṣe ṣekú pa igbákejì Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́, tí wọ́n sọ pé ó ń gbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ọmọ lákòókò ìkọlù tó wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Oríire, nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.

Ẹgbẹ́ CAN wòye pé kò yẹ kí ìfararúbọ igbákejì Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún di ohun ìgbàgbé, wọ́n sì gba ìjọba àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò níyànjú láti ríi dájú pé wọ́n ṣe àwárí àwọn oníṣẹ́ ibi náà, kí wọ́n gbá wọn mú, kí wọ́n sì fi imú wọn káta òfin.

Nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Ààrẹ Ẹgbẹ́ CAN ní oríléèdè Nàìjíríà lápapọ̀, Archbishop Daniel Okoh, ni Ẹgbẹ́ ọ̀hún ti fi àìdùnnú hàn sí bí wọ́n ṣe mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn olùkọ́ àti àwọn alákòóso ilé ẹ̀kọ́ sí ìgbèkùn, wọ́n sì ṣàpèjúwe ìkọlù náà gẹ́gẹ́ bíi nǹkan ìbanilójújẹ́ fún oríléèdè Nàìjíríà àti àpẹẹrẹ ìbẹ̀rùbojo ipò tí ìṣòro ètò ààbò tí burú jáì tòó.

Ẹgbẹ́ CAN kọminú pé àwọn agbébọn kọlu àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti agbègbè, wọ́n sì mú orí bọ́, débi wípé wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ lọ, èyí tí wọ́n tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bíi nǹkan tó ju pé ètò ààbò ti yinjẹ lọ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ohun tó ṣe àpẹẹrẹ pé ìwà ọ̀daràn náà ti ń pẹ̀ka wọ àwọn ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ láti ẹ̀yìn pé ààbò dè.

Ẹgbẹ́ ọ̀hún wá dá àbá pé ó ti tó àkókò kí ìjọba máa dáàbò bo àwọn ilé ẹ̀kọ́ pàápàá jù lọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ń bẹ láwọn ìgbèríko, kí wọ́n ṣe àfikún àwọn ikọ̀ alaabo tí yóò má a pèsè ààbò láwọn igbó kìjikìji tí àwọn oníṣẹ́ láabi le má a fi ṣe ibùba.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *