SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ọkọ̀ Kan Ìyàwó Lẹ́ṣẹ̀ Pa Nílùú Èkó

arrested handcuffed 2

Enimere Àkànbí
Ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kànlélógójì, Uchenna Aghoha, ni wọ́n sọ pé ó kan aya rẹ̀, Esther, ní ẹ̀ṣẹ́ pa, lákòókò àríyànjiyàn tó wáyé láàrin wọn ní agbègbè Satellite Town, nípìnlẹ́ Èkó.

Àwọn oníròyìn ríi gbọ́ pé ọjọ́ ẹtì tó kọjá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, láti ara ìfọwọ́gbọ́nà mùni nínú ìgbéyàwó.

Ìgbójú aágan síra ẹni ló wáyé láàrin tọkọtaya ọ̀hún lákòókò àríyànjiyàn tó padà di ìjà mọ́ wọn lọ́wọ́.

Ẹni kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣojú rẹ̀, tí kò fẹ́ dárúkọ ara rẹ̀ ṣàlàyé pé lákòókò tí Aghoha, ń kan Esther, ní ẹ̀ṣẹ́, ló gbé ẹ̀mí mì mọ́ ọ lọ́wọ́.

Ó sọ pé “ìgbójú aágan síra láàrin tọkọtaya ọ̀hún kò jẹ́ nǹkan tuntun sí àwọn, tí àwọn sì rò pé bí wọ́n ṣe má a ń ja ìjà wọn náà ni, nígbà tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ ẹtì. Nígbà tí ọmọ wọn obìnrin sá jáde láti inú ilé wọn, tó sì ké gbàjarè pé ìyá òun ti dákú lákòókò tí bàbá òun ń kàn-án ní ẹ̀ṣẹ́. A sáré dé ibẹ̀, tí a sì ríi pé kò mira mọ́”

Onítọ̀hún fi kún un pé wọ́n gbé abílekọ ọ̀hún dìgbà dìgbà lọ sí ilé ìwòsàn, tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ó ti kú.

Ọmọdébìnrin ọdún mẹ́rìnlá tó jẹ́ ọmọ wọn, ló fi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó àwọn ọlọ́pàá létí, tí àwọn ọlọ́pàá sì gbéra lọ síbẹ̀, níbi tí wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀ fún wọn pé, wọ́n ti gbé obìnrin náà lọ sí ilé ìwòsàn ikọ̀ ológun orí omi, níbi tí oníṣègùn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti kú.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, Adébísí Abímbọ́là, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, fi kún pé àwọn ọlọ́pàá tó lọ síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti wáyé, ya àwòrán olóògbé àti ẹni tí wọ́n fura sí.

Ó ṣàlàyé pé “ẹni tí wọ́n fura sí ti wà lákàtà ọlọ́pàá. Wọ́n sì ti gbé òkú arábìnrin ọ̀hún lọ sí ibùdó ìgbókù sí, ní ilé ìwòsàn ńlá ìjọba tó ń bẹ ní agbègbè Yábàá. Wọn yóò fi ọ̀ràn náà ráńṣẹ́ sí ẹ̀ka tó ń ṣe ìwádìí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀daràn, ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, tó ń bẹ ní Pàǹtí, fún ìwádìí kíkún.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *