SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Ọlágúnjú Gba Àwọn Ọ̀ṣíṣẹ́ OYSIEC Níyànjú Láti Fọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹ̀lú Alága Tuntun

IMG 20250914 WA0008

Enimere Àkànbí
‎Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, péjọ láti bọ̀wọ̀ fún ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yẹ̀bá kúrò nípò Alága Àjọ Elétò Ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (OYSIEC), Ààrẹ Isiaka Ọlágúnjú, SAN, fún àtìlẹyín tí Ẹgbẹ́ náà jẹ àǹfààní rẹ̀ àti àwọn àṣeyọrí gbogbo tí Àjọ ọ̀hún ṣe ní àkòókò rẹ̀.

‎Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò ráhánpẹ́ ọ̀hún, tó wáyé ní olúléṣẹ́ Àjọ OYSIEC, ní ìlú Ìbàdàn, Alága Ẹgbẹ́ náà, Ọ̀mọ̀wé Olúṣẹ́gun Ọdẹ́kúnlé, ṣàlàyé pé àwọn pinnu láti bu ọlá fún Alága tẹ́lẹ̀ náà, nítorí bí ó ṣe ríi dájú pé Àjọ ọ̀hún ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní ẹ̀mẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ọ̀fọ́n-àn kankan kò sì fi irú na igbá.

‎Nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Ọdẹ́kúnlé, ń sọ nípa ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú u Àgbà-ọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rọ̀ náà, Ààrẹ Ọlágúnjú, ó dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, fún àtúngbéyẹ̀wọ̀ àwọn àjẹmọ́nú àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ Àjọ ọ̀hún tó ṣe láìpẹ́ yìí.

‎Bákan náà ló lo àkókò yìí fi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìpèsè àfikún àwọn irinṣẹ́ ìdìbò, kí iṣẹ́ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ Àjọ OYSIEC leè túnbọ̀ mú yányán síi.

‎Nígbà tí Ààrẹ Isiaka Ọlágúnjú, SAN, ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yẹ̀bá kúrò nípò Alága Àjọ OYSIEC, ń fèsì, ó fi ìdùnnú hàn sí bí àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ Àjọ náà ṣe ṣiṣẹ́ takuntakun làwọn àkókò tí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

‎Ààrẹ Ọlágúnjú, tó tọ́ka sí àṣeyọrí ètò ìdìbò tó wáyé lẹ́mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ìjọba ìbílẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìmúṣẹ àgbékalè òfin ìdìbò tí àwọn ikọ̀ òun tẹ́lẹ̀, ó sì gba àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ Àjọ OYSIEC níyànjú láti fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹni yòówù tí wọ́n bá yàn láti jẹ́ Alága wọn tuntun, fún àǹfààní àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ìdàgbàsókè rẹ̀.

‎Nínú ọ̀rọ̀ ti Ẹ̀ náà, Akọ̀wẹ́ àgbà Àjọ OYSIEC, Arábìnrin Abísọ́lá Ògúnmọ́lá, pé fún ìtẹ̀sìwájú àjọṣe pọ̀ tó gúnmọ́ láàrín àwọn alákòóso ètò ìdìbò àti àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ Àjọ náà, kí àṣeyọrí iṣẹ́ ìríjú wọn le máa tó wọn lọ́wọ́.

IMG 20250914 WA0009 300x225

‎Níbi ètò náà tí wọ́n ti fún àwọn tó yẹ ní ẹ̀bùn àti àkànṣe àdúrà, ni àwọn alákòóso ètò ìdìbò láti ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó ń bẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ Ààrẹ Ọlágúnjú, àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ Àjọ OYSIEC, péjúpésẹ̀ sìí.


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *