Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ti lérí pé àwọn yóò kó ara àwọn jọ fún ìyánṣẹ́lódì tí kò ní gbèdéke káàkiri oríléèdè yìí, nítorí ètò ààbò oríléèdè yìí tó ti di apẹ̀rẹ̀ ajáàdí àti ọ̀rọ̀ owó oṣù tí kò tíì yanjú.
Ẹgbẹ́ ọ̀hún nínú àfẹnukò ìpàdé tí wọ́n kà lẹ́yìn ìpàdé ojú ayélujára tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, níbi tí wọ́n ti fi àìdùnnú hàn sí Àgbáríjọpọ̀ Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, NLC, àti Ẹgbẹ́ àwọn lọ́gàlọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba, TUC, pé wọn kò ṣe ojúṣe wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́.
Nínú àfẹnukò ìpàdé ọ̀hún tí alákòóso ètò Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ọba lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Messrs Emelieze àti akọ̀wé Ẹgbẹ́ ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Ayọ̀ Ògúndélé, bu ọwọ́ lù nílùú Ìbàdàn, tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ẹgbẹ́ náà ti fi ẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé wọ́n ń lo àwọn òṣìṣẹ́ fún èrè ara wọn àti pé wọ́n tún kùnà láti pèsè ààbò tó dájú fún àwọn aráàlú.
Ẹgbẹ́ náà sàlàyé pé nígbà tí àwọn ṣe ètò ìdìbò ojú òpó ayélujára láti fi ṣe ìpinnu lórí ọ̀nà àbáyọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yòókù ló fọwọ́ síi pé kí àwọn da iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ìnira tí àwọn aráàlú ń kojú àti ìṣòro ètò ààbò níbi gbogbo lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, pẹ̀lú àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù tí wọ́n ṣe nínú oṣù keje ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìnlélógún ni wọ́n fi tan àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ jẹ.
Wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà ni wọ́n fi kún owó oṣù gbogbo ìsòrí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀, tí wọ́n sì tún ń yọ owó orí nínú rẹ̀, èyí tí kò jẹ́ kí àléékún owó náà nítumọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba.
Ẹgbẹ́ ọ̀hún tún sọ pé ìdá ogójì owó àjẹmọ́nú (Peculiar allowance) tí olórí òṣìṣẹ́ ọba Arábìnrin Didi Walson-Jack, ṣèlérí pé ìjọba àpapọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san láti ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù karùn-ún ọdún yìí, ni ẹ̀ka olùṣirò owó àgbà padà sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀.
Wọ́n fi kún àlàyé wọn pé ìjọba àpapọ̀ ti san owó oṣù karùn-ún, ṣùgbọ́n kò sí owó àjẹmọ́nú tí Alákòóso ìṣúná ṣèlérí àti pé àwọn kò rí àléékún owó oṣù gbà.
Ẹgbẹ́ ọ̀hún fi kún-un nínú àfẹnukò ìpàdé ọ̀hún pé, àìrí àjẹsílẹ̀ owó ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ àti àwọn ẹ̀tọ́ míì gbà, ti mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ lára.
Sẹ́gun Adélakùn












Leave a Reply