Enimere Àkànbí
Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀ Kano ti ba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá, ti ilé ẹ̀kọ́ Government Boarding Secondary School, Bichi, fún ẹ̀sùn tó ní ṣe pẹ̀lú ìṣekúpa méjì nínú àwọn akẹgbẹ́ wọn.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀ Kano, Ọ̀gbẹ́ni Abdullahi Haruna, ló fìdí ìgbésẹ̀ yìí múlẹ̀ fún PUNCH Online, láti orí àtẹ̀jíṣẹ́.
Ọ̀gbẹ́ni Haruna, jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ti fi ìbéèrè pọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìfun pọ̀, láti mọ́ ipa tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n kó nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá ọ̀hún, ṣe ìlérí pé àwọn yóó sa gbogbo ipá àwọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí gbogbo àwọn tí aje ìwà ìbàjẹ́ bá ṣí mọ́ lórí yóó gbọ̀ òórùn ara wọn.
Ṣáájú ní Ọjọ́rú, ni aláàkóso ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Kano tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ètò ẹ̀kọ́, Ọ̀mọ̀wé Ali Haruna Makoda, pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọ̀rìnkínníwín ìwádìí nípa nǹkan tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fi àṣẹ náà rán akọ̀wé àgbà ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìjọba ọ̀hún, Bashir Bappa Mohammad, tó ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀uń ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé, wọ́n lọ ṣígun bá Hamza Idris Tofawa àti Umar Yusuf Dungurawa, tí wọ́n sì fi àwọn nǹkan ìjà abẹ́lé tí wọ́n ń pè ní “Gwale-Gwale” gba ẹ̀mí wọn.
Ọwọ́ Iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá Ìpínlẹ̀ Kano Ba Akẹ́kọ̀ọ́ Mọ́kànlá Fún Ẹ̀sùn Ìṣekúpa Àwọn Akẹgbẹ́ Wọn











Leave a Reply