Enimere Àkànbí
Àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré nnì, tó tún jẹ́ ògbóǹkangí olùkọ́ni nípa eré orí ìtàgé, Olóyé Kọ́lá Gabriel Oyèwọ̀, ti jáde láyé, lẹ́ni ọgọ́rin ọdún.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ olóògbé, Adétóyèṣe Oyèwọ̀, ló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde tí Ọ̀mọ̀wé Adéwálé Oyèwọ̀, kọ lórúkọ gbogbo ẹbí Oyèwọ̀.
Bákan náà ni ọ̀kan lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré, Kúnlé Afod, fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ lójú òpó ayélujára.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi òpin sí iṣẹ́ takuntakun tí Bàbá Oyèwọ̀, ti ń ṣe bọ̀ lẹ́ka amúlùúdùn oríléèdè Nàìjíríà láti bíi ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn.
Ọjọ́ keje, oṣù kẹta ọdún 1946, ni wọ́n bí olóògbé ní ìlú Ọba-Ilé, nípìnlẹ́ Ọ̀ṣun, tí Bàbá sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ nínú eré oríìtàgé lọ́dún 1964, nígbà tó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Oyin Adéjọbí Theatre Group.
Láti bíi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Bàbá Oyèwọ̀ ti di ọ̀kan lára àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ lágbo òṣèré oríléèdè Nàìjíríà, pàápàá jù lọ lẹ́ka àwọn tó ń fi èdè Yorùbá ṣe iṣẹ́ náà, láti ara bí ó ṣe má a ń lo àṣà, ìṣe àti èdè Yorùbá fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣe tọ́.
Bákan náà ni olóògbé jẹ́ Balógun ìlú Ọba-Ilé, tó jẹ́ ìlú abínibí rẹ̀.
Oyèwọ̀ di ìlúmọ̀ká òṣèré láti ara ipa ribiribi tó kó nínú eré tí Ọlá Rótìmí kọ, tó pè ní The Gods Are Not to Blame, nínú èyí tó ti kópa gẹ́gẹ́ bíi Ọdẹ́wálé.
Ó tún fi onírúurú ẹ̀bùn hàn nínú àwọn eré bíi Ṣaworo-idẹ, Ṣàngó, Kóṣeégbé àti eré tí wọ́n ma ń ṣe àfihàn rẹ̀ lọ́sọ̀sẹ̀ nígbà kan lórí àwọn iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán, Super Story.
Ẹ̀bùn àti ìwà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó fi ma ń ṣe iṣẹ́ ọ̀hún mú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú aláìlẹ́gbẹ́ bá ẹ̀ka amúlùúdùn oríléèdè Nàìjíríà, kódà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tó ti làmìlaka ló wòó kọ́ṣe.
Bákan náà ni olóògbé jẹ́ ọ̀mọ̀wé, láti ara bí ó ṣe kẹ́kọ̀ọ́ gboyègbẹ̀yẹ nípa eré orí ìtàgé àti alágbèléwò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ilẹ̀ Ìbàdàn, tó sì tún fi ìmọ̀ ọ̀hún bọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ bíi, ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, OAU, ti ìlú ilé ìfẹ́, nípìnlẹ́ Ọ̀ṣun, ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ìlú Ìlọrin, ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ti Redeemer àti ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Elizade.
Láti bíi ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn ni olóògbé, Olóyé Kọ́lá Gabriel Oyèwọ̀, ti ń sọ nípa ìrírí àti ìdojúkọ rẹ̀ pẹ̀lú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ìtọ̀ ọkùnrin, kí ọlọ́jọ́ tó dé lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù kẹfà, ọdún 2026.











Leave a Reply