SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ikọ̀ Agbébọn Pa Ọlọ́pàá Méjì Nípìnlẹ́ Anambra

images (3)

Enimere Àkànbí
Ikọ̀ agbébọn kan kọlu àwọn ọlọ́pàá ní òpópónà Amansea-Ndiukwuenu -Awa-Ufuma, ní ìjọba ìbílẹ̀ gúúsù Orumba, nípìnlẹ́ Anambra, tí wọ́n sì rán ọlọ́pàá méjì ní ìrìnàjò àrèmábọ̀ lójú ẹsẹ̀.

Ìwádìí àwọn oníròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n sẹ́bùrú àwọn ọlọ́pàá náà lákòókò tí wọ́n ń padà bọ̀ láti ibi iṣẹ́ ní alẹ́ ọjọ́ àìkú.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣojú wọn ṣe sọ, àwọn agbébọn náà tó fi ara pa mọ́ sí inú igbó, ṣíná ìbọn fún àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún, tí ìró ìbọn wọn sì mú ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ará agbègbè náà.

Ọ̀kan lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣojú wọn, tó jẹ́ ẹni tó ń wa kẹ́kẹ̀ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta, tó gba ojú ọ̀nà ọ̀hún kọjá, ṣùgbọ́n tí kò dárúkọ ara rẹ̀, ṣàlàyé pé nígbà tí òun ń padà bọ̀ láti Ezira, níjọba ìbílẹ̀ gúúsù Orumba, ni òun gbọ́ ìró ìbọn lójijì, lójú ẹsẹ̀ ni òun yíjú padà fún ààbò ara òun.

Ó fi kún-un pé lẹ́yìn ìgbà tí ìró ìbọn náà rọlẹ̀ ni òun mú ìrìnàjò òun pọ̀n padà, nígbà tí òun yóò fi dé ọ̀gangan ibi tí wón ti yìbọn, òkú àwọn ọlọ́pàá méjì tí wọ́n yìbọn pa ni òun bá nílẹ̀.

Fónrán amóhùnmáwòrán kan tó di tọ́rọ́fọ́nkálé lójú òpó ayélujára, ṣàfihàn òkú àwọn ọlọ́pàá méjèèjì nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ìpàáro wọn, pẹ̀lú ohùn ẹnìkan tó ń pè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn aláṣẹ tọ́rọ̀ kàn.

Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn kàn sí àwọn tọ́rọ̀ kàn ní ọjọ́ Ajé, tí ṣe ọjọ́ kejì tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣẹlẹ̀, Ọ̀gá ọlọ́pàá nípìnlẹ́ Anambra, Ọ̀gbẹ́ni Ikioye Orutugu, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ìkọlù ọ̀hún wáyé lóòtọ́.

Ọ̀gbẹ́ni Ortugu, sàlàyé pé àwọn ti ń ṣe ìwádìí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tó fi mọ́ àwọn ìgbésẹ tó ṣe pàtàkì.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ikọ̀ ọlọ́pàá tí wọ́n ń darí bọ̀ láti ibi iṣẹ́ ni àwọn oníṣẹ́láabi ọ̀hún dá lọ́nà tí wọ́n sì mú méjì nínú àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún balẹ̀, pẹ̀lú àfikún pé àwọn ti ń ṣe akitiyan láti mọ àwọn tó ń bẹ lẹ́yìn ìkọlù yìí.

Ọ̀gá ọlọ́pàá ọ̀hún jẹ́ kó di mímọ̀ òun yóò ṣàbẹ̀wò sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, láti wo bí nǹkan ṣe rí àti láti fi inúkonú pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò lórí ọ̀nà tí àwọn leè dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún nípìnlẹ́ Anambra.

Ò sì tún ṣèkìlọ̀ fún àwọn awakọ̀ àti àwùjọ lápapọ̀ láti má a ṣọ́ra ṣe àti pé kí wọ́n má ṣe lọ sí àwọn agbègbè tí kìí ṣe àwọn agbófinró ló fi òǹtẹ̀ lù fún àyẹ̀wò àwọn ọkọ̀ tó ń kọjá.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *