Enimere Àkànbí
Igbákejì Ààrẹ nígbà kan rí lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Atiku Abubakar, ti bu ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Bọlá Tinúbú àti Aya rẹ̀, Olúrẹ̀mí Tinúbú, fún bí àwọn tí wọ́n jígbé nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́ kò ṣe tíì kúrò ní àkàtà àwọn agbébọn.
Ààrẹ Oludije fún ẹgbẹ òṣèlú African Democratic Congress, Atiku Abubakar sọrọ si ìjọba àpapọ fun kuku na aigbe ìgbésẹ tó yẹ lati gba awon to lugbadi nínú iṣẹlẹ na.
Nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ àgbà lórí ọ̀rọ̀ ìbàrálúsọ̀rọ̀, Phrank Shaibu, ni Atiku ti sọ pé ọ̀rọ̀ òṣèlú múmú làyà ìṣàkóso Ààrẹ Tinúbú, ju ìpọ́njú tó bá àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé lọ.
Atiku, tí Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC yàn gẹ́gẹ́ bíi olùdíje ipò Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, sọ pé ipò Adarí kìí ṣe dídí gẹrẹwu lásán, bí kò ṣe láti fi ìkáànú hàn lákòókò tí àwọn aráàlú bá wà nínú ìdojúkọ.
Bákan náà ni Atiku, fẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú dé ọ̀dọ̀ Aya Ààrẹ, Olúrẹ̀mí Tinúbú, pé ohun tí àwọn ọmọ Nàìjíríà retí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìfọnrere gbọ́nmọ gbọ́nmọ fún ìdọ́ọ̀là àwọn tó ń bẹ́ nígbèkùn àwọn ajínigbé.
Ó fi kún-un pé ètò òṣèlú àti afẹfẹyẹ̀yẹ̀ kò yẹ kó bo ìgbìyànjú láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ ọ̀hún sílẹ̀.
Atiku, kọminú pé irú ìyá wo ni yóò fojú borun, jó, tàbí ṣe àjọyọ̀ ìyege nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú, gba àwọn Ẹgbẹ́ tó ń ṣe ìpolongo òṣèlú lálejò, pín àwọn ọkọ̀ olówó iyebíye fún àwọn alábàáṣepọ̀ nínú òṣèlú, nígbà tí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ wọn wà nígbèkùn àwọn ajínigbé.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply