Enimere Àkànbí
Ajìjàgbara yorùbá, Olóyè Sunday Adéyẹmọ, tọ́pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Sunday Ìgbòho, ti ṣèlérí láti kéde orúkọ àwọn olóṣèlú tó mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Oríire nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, síta fún aráyé gbọ́.
Nígbà tí Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, tí Ààrẹ wọn Babátúndé Akíntẹ́yẹ, léwájú lọ sọ́dọ̀ Ajìjàgbara náà, nílé rẹ̀ tó ń bẹ ní agbègbè Sókà, nílùú Ìbàdàn, sọ̀rọ̀, ni Olóyè Adéyẹmọ, ṣàlàyé pé òun dìídì yòǹda ara òun láti lé àwọn agbésùnmọ̀mí ọ̀hún léré, ṣùgbọ́n ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé rárá.
Ọ̀rọ̀ ọ̀hún tó di tọ́rọ́fọ́nkálé lójú òpó ayélujára, ni Sunday Ìgbòho, ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun kò bèèrè owó kankan lọ́wọ́ ìṣàkóso Gómìnà Ṣèyí Mákindé, láti fi gba àwọn tó ń bẹ nígbèkùn àwọn ajínigbé sílẹ̀.
Ó sọ pé bí wọ́n bá gba òun láàyè láti lọ kojú àwọn agbésùnmọ̀mí ọ̀hún ní ibùba wọn, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé èèyàn ni wọ́n, tí wọn kì í ṣe ọmọláńgidi, òun yóò lé wọn jáde níbi kọ́lọ́fín wọn.
Ajìjàgbara náà fi kún-un pé òun yóò dárúkọ àwọn olóṣèlú gbogbo tó mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe kọlu àwọn ilé ẹ̀kọ́ mẹ́tààta ọ̀hún, bí wọn kò bá dá ọwọ́ ìwà ìbàjẹ́ wọn dúró, pàápàá jù lọ àwọn tó ń pèsè owó àti àwọn nǹkan ìjagun fún àwọn agbébọn.
Nítẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ìgbòho sọ pé irú nǹkan tí wọ́n ṣe nígbà ìṣàkóso Ọ̀mọ̀wé Goodluck Jonathan, náà ni wọ́n fẹ́ ṣe láti fi bá ìjọba Ààrẹ Bọlá Tinúbú jẹ́, àti pé gbogbo ìgbìyànjú àwọn ẹni ibi, ni láti jẹ́ kó nira láti ṣe ìṣàkóso oríléèdè Nàìjíríà.
Ajìjàgbara ọ̀hún tó fi ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe ibùjókòó, ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́ sí ìdásílẹ̀ ikọ̀ aláàbò òun, Ìrùn Ẹkùn, ṣùgbọ́n ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kìlọ̀ fún òun pé ìgbìyànjú òun tàbí ti ẹnikẹ́ni láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ náà là, leè yọrí sí ikú wọn.
Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ohun tó jẹ òun lógún jù ni àwọn tí wọ́n jígbé, ó sì fi ìgboyà sọ pé kò sí ẹni náà tó leè jí òun tàbí àwọn ẹbí òun gbé lọ, nítorí pé ìlú Canada àti oríléèdè Germany ni àwọn mọ̀lẹ́bí òun wà, kò sí ohun tí yóò má a ba òun lẹ́rù.
Sunday Ìgbòho fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bí ìṣàkóso olóògbé Muhammadu Buhari, ṣe burú jáì tòó, ó ṣe é parí, ó wá bèèrè pé, kí ló dé tí wọ́n fẹ́ pa igi dínà Tinúbú tó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá.
Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé Ààrẹ Tinúbú, ló ran òun lọ́wọ́ nígbà tóun jẹ́ ẹni tí ilé kò gbà, tọ́nà kò gbà, nítorí ìdí náà, òun kò leè takòó, àyàfi àwọn tó fẹ́ ba ìjọba rẹ̀ jẹ̀ẹ́.
Ẹ ó rántí pé ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù karùn-ún, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ni àwọn agbébọn jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń lọ bíi márùndínláàdọ́ta níye gbé lọ, lákòókò ìkọlù tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, níjọba ìbílẹ̀ Oríire, nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply