Enimere Àkànbí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ti túbọ̀ fi ìgbáradì hàn láti ṣe ìfararúbọ tàbí lo gbogbo ohun tó bá gbà láti fi gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí àwọn agbébọn jígbé padà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn láyọ̀ àti àlàáfíà.
Gómìnà Mákindé fi ìmúratán yìí hàn lákòókò tó ń bá àwọn tí gbajúmọ̀ Ajàjàgbara nnì, Martins Otse, tọ́pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí VeryDarkMan(VDM) léwájú lọ ṣe ìfẹ̀hùnúhàn àlàáfíà ní ilégbèé rẹ̀ tó ń bẹ ní agbègbè Ìkọ́làbá, nílùú Ìbàdàn.
Gómìnà Mákindé tó jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun ṣe tán láti tẹ́lẹ̀ àwọn ikọ̀ tó bá fẹ́ lọ dọ́làà àwọn tó ń bẹ nígbèkùn, ṣàlàyé pé ibi ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí nílò ìpinnu àti igbésẹ̀ akin.
Mákindé, tó jẹ́ kó di mímọ̀ pé nínú ìgbìyànjú láti dọ́làà àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ikọ̀ aláàbò ló ti fara gbá a, fi ìgboyà sọ pé láìpẹ́ ni wọn yóò padà sílé wọn ní àlàáfíà.

Gómìnà Mákindé, tó fi ògún rẹ̀ gbárí fún àwọn olùfẹ̀hùnúhàn pé, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò leè dà bíi irú èyí tó wáyé nílùú Chibok, jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjọba ìpínlẹ̀ kò láṣẹ lórí àwọn ikọ̀ aláàbò tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó ṣẹ́nu kù nípa ìgbésẹ̀ àwọn ikọ̀ aláàbó, fi àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́kàn balẹ̀ pé àlàkalẹ̀ ètò ààbò tó ń bẹ nípìnlẹ́, kájú rẹ̀ láti fi gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ kúrò lákàtà àwọn agbébọn àti láti pèsè ààbò tó péye fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn aráàlú.
Ó sì dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn olùfẹ̀hùnúhàn fún akitiyan, ìwà akíkanjú àti ìwà ọmọlúwàbí tí wọ́n fi hàn nínú ìwòde ọ̀hún tí wọ́n ṣe, láì bá ohunkóhun jẹ́.
Ṣáájú nígbà tó ń gba ẹnu àwọn olùfẹ̀hùnúhàn ọ̀hún sọ̀rọ̀, VDM, ṣàlàyé pé àwọn fẹ́ mọ ohun tí ìjọba ń ṣe, tí ọ̀rọ̀ náà fi falẹ̀ tó báyìí àti pé àwọn ti ṣe tán láti tẹ́lẹ̀ àwọn ikọ̀ aláàbò lọ sínú igbó ńlá náà, nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ gba àwọn tó ń bẹ nígbèkùn sílẹ̀.
Bákan náà ló gba ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ìjọba àpapọ̀ níyànjú láti jára mọ̀ ìgbésẹ̀ gbogbo láti gba àwọn ènìyàn ọ̀hún là, pẹ̀lú àfikún pé, kò gbọdọ̀ dà bíi ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok.
Ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kàrún-un, ni àwọn agbébọn kọlu ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní agbègbè Ahoro-Ẹ̀sínẹ̀lẹ̀ àti Yáwóta, níjọba ìbílẹ̀ oríire, nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply