Enimere Àkànbí
Ìròyìn jẹ́ kó di mímọ̀ pé ikọ̀ agbésùnmọ̀mí gbójúgbóyà débi pé wọ́n gbé òkú Ajagunfẹ̀yìntì Rabe Abubakar, lọ fún àwọn ẹbí rẹ̀ nípìnlẹ́ Katsina, tí wọ́n sì gba inú igbó ńlá kan tó ń bẹ níjọba ìbílẹ̀ Matazu, padà lọ, láì rí ẹni dá wọn dúró.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn, ṣàlàyé pé ní àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ àìkú ni wọ́n gbé òkú ọ̀hún sílẹ̀.
Ìpadà àwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí náà láì sí ẹni tó yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ lò, túbọ̀ mú àwọn ọmọ Nàìjíríà kọminú nípa ipò tí ètò ààbò wà.
Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ kò fèsì nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n ti sin òkú Ajagunfẹ̀yìntì Abubakar, ní ìlànà mùsùlùmí.
Ẹ̀wẹ̀ àwọn ọmọ olóògbé ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àpapọ̀ láti fi kún akitiyan wọn láti gba ìyá àwọn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Ṣáájú ni Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà, Bọlá Tinúbú, fi ìbànújẹ ọkàn hàn sí ìpapòdà ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ Adarí ẹ̀ka ìròyìn fún iléeṣẹ́ ológun, Ọ̀gágun Rabe Abubakar, ti ìròyìn ikú rẹ̀ lákàtà àwọn agbébọn nípìnlẹ́ Katsina, kan àwọn aráàlú ku.
Nínú àtẹ̀jáde láti iléeṣẹ́ Ààrẹ, ni Ààrẹ Tinúbú, ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún bá òun lẹ́jafùú àti pẹ̀lú ìbànújẹ ọkàn, ó sì ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi nǹkan ìbànújẹ tó ń rán ni létí ìdojúkọ ètò ààbò tí ó ń kojú àwọn apá ibì kan lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Ọ̀gagun Abubakar, tó jẹ́ ajagunfẹ̀yìntì, ni àwọn ajínigbé mú òun àti aya rẹ̀ sákàtà lákòókò tí wọ́n ń rin ìrìn àjò lọ sípìnlẹ́ Katsina, tó jẹ́ ìlú abínibí wọn.
Iléeṣẹ́ Ààrẹ tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìyàwó olóògbé tí wọ́n jọ jí wọn gbé, ṣì wà lákàtà àwọn agbésùnmọ̀mí ọ̀hún, èyí tó ń mú kí àwọn aráàlú túbọ̀ má a kọminú.
Ààrẹ sì bá ìdílé náà, awọn olùgbé ìpínlẹ̀ Katsina àti iléeṣẹ́ ológun, kẹ́dùn, ó sì ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun tí kò yẹ.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply