Enimere Àkànbí
Ọmọba Al-Waleed bin Khaled bin Talal Al Saud, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “Sleeping Prince ti ilẹ̀ Saudi Arabia” ti padà gbé ẹ̀mí mì ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì, ní ẹ̀yìn ogún ọdún tó ti wà lórí ìbùsùn ilé ìwòsàn, láìmọ̀ bọ́yá ayé ni òun wà àbí ọ̀run, nítorí ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ síi ní ọdún 2005, ní ìlú London.
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn TheSunUK, ṣe kọ́, Bàbá tó bí ọmọ náà, Ọmọba Khaled bin Talal bin Abdulaziz, ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lójú òpó ayélujára X pé Ọjọ́kọkàndínlógún, oṣù keje, ọdún 2025, ni Ọmọ Ọba náà tí ìjàmbá ọkọ ọ̀hún tó wáyé ní àkókò tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ ológun ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ṣe àkóbá fún ọpọlọ rẹ̀ (brain hemorrhage) gbé ẹ̀mí mì.
Lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ náà ní ogún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n gbé Ọmọba Al-Waleed, lọ sí ilé ìwòsàn King Abdulaziz Medical City ní ìlú u Riyadh, tí ó sì sùn bọrọgidi kalẹ̀ ní àìlajú, sọ̀rọ̀ tàbí mira láti ìgbà náà, ṣùgbọ́n wọn kò dá ọwọ́ ìpèsè ìlera dúró ní ara rẹ̀, tí àwọn ẹ̀rọ agbẹ́mìró náà kò sì sinmi iṣẹ́.
Onírúurú àwọn onímọ̀ ìlera káàkiri àgbáyé ni wọ́n bẹ́ lọ́wẹ̀ ní àárín ogún ọdún tí ọmọ náà fi ń gba ìtọ́jú ní ipò tó wà, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú wọn ló fi orí ṣánpọ̀n.
Bí ọjọ́ ṣe ń gun orí ọjọ́, ni Bàbá rẹ̀, Prince Khaled, kò sọ ìrètí nù, tó sì ń ná owó, àti gbogbo nǹkan tó gbà láti le è gbé ẹ̀mí ọmọ náà ròó, pàápàá jù lọ, kó kúrò ní ẹṣẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run tó wà.
Kódà ìwádìí fikùn pé Prince Khaled, kò fi etí sí àwọn onímọ̀ ìlera tó gbàá ní ìmọ̀ràn láti gbé rẹ̀, Prince Khaled, kúrò lórí àwọn ẹ̀rọ agbẹ́mìró.
Ṣùgbọ́n, ní báyìí Ọmọba Al-Waleed bin Khaled bin Talal Al Saud, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “Sleeping Prince ti ilẹ̀ Saudi Arabia” ti padà di èrò ọ̀run.
Nigerian Tribune
Ọmọba Saudi Tó Sùn Bọrọgidi Láìsọ̀rọ̀, Mira Níléwòsàn Fún Ogún Ọdún, Padà Kú














Leave a Reply