SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ebi, Ìṣẹ́, Òṣì Kò Bá Aráàlú Múlẹ̀ Tó Bí Wọ́n Ṣe Ń Fẹnu Sọ́ – Olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ

hq720

Enimere Àkànbí
Olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà, Bọlá Tinúbú, lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Báyọ̀ Ọnànúgà, ti pọ̀n sẹ́yìn ìjọba lórí ìlànà ọrọ̀ ajé tí ìṣàkóso tó ń bẹ lóde ń gbé kalẹ̀, pẹ̀lú àfikún pé òun kò rí ìṣẹ́ àti òṣì táwọn ọmọ Nàìjíríà ń fi gbogbo ìgbà sọ pé ó ń bá àwọn fínra.

Ọ̀gbẹ́ni Ọnànúgà, sọ̀rọ̀ yìí lákòókò tó ń kópa lórí ètò iléeṣẹ́ àmóhùnmáwòrán Arise, pẹ̀lú àwíjàre pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò àti àkànṣe iṣẹ́ amáyédẹrùn tí ìjọba ń gbé kalẹ̀ ti ń mú ìdẹ̀rùn àti mùkúndùn ìjọba dé ọ̀dọ̀ àwọn aráàlú níbi gbogbo lórílẹ̀èdè yìí.

Nígbà tó ń fi àwọn àkànṣe iṣẹ́ amáyédẹrùn bíi ojú ọ̀nà, iná sòrudọ̀sán àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tó rí tí ìjọba ṣe lákòókò kan tó rin ìrìn àjò láti ìlú Ìbàdàn lọ sí Èkó, èyí tí súkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ mú u gba ọ̀nà Ṣàgámù kọjá lọ sí Ìjẹ̀bú òde, ṣe àpẹrẹ, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé, àwọn ohun mèremère tí ìjọba ti ṣe, ti mú àwọn aráàlú mẹ́nu mọ́.

Bákan náà ló tọ́ka òpópónà másọsẹ̀ létí omi òkun tí ìjọba àpapọ̀ ń ṣe lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bíi ohun tó ti mú ìdẹ̀rùn bá lílọ bíbọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ aráàlú, tó fi mọ́ òun fúnra rẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Ọnànúgà, tún ṣàpèjúwe ètò owóyàá tí ìṣàkóso Ààrẹ Tinúbú gbé kalẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ẹ̀yáwó tí èlé rẹ̀ kò gún pa fún àwọn òṣìṣẹ́, gẹ́gẹ́ bíi ara ìlànà tí ìjọba ń gbé kalẹ̀ láti mú ìtura owónàá bá àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ó fi kún-un pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn aráàlú bá ń ṣe ìjíròrò nípa ọrọ̀ ajé, wọn kìí mẹ́nu ba àwọn nǹkan tí wọ́n ti jẹ lérè nínú ìṣàkóso ẹni tó ń bẹ nípò.

Ọnànúgà, sọ pé ohun tí àwọn aráàlú gbọ́ nínú fọ́nrán ohùn kan tí ẹnì kan ṣe lákòókò kan tí Ààrẹ Tinúbú ṣe àbẹ̀wò lọ sí ìlú Èkó, tí onítọ̀hún sọ pé “Ebi ń pa wá ó” ni àwọn ọmọ Nàìjíríà náà ń mú sẹ́nu títí di òní.

Olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ náà tó gbà pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣì ń kojú ìṣòro ọrọ̀ ajé, tẹnu mọ́ ọ pé ìbáṣepọ̀ òun pẹ̀lú aráàlú kò fi hàn pé ìṣẹ́ àti òṣì ń bá àwọn aráàlú mulẹ̀ tó bí wọ́n ṣe ń fi ẹnu sọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *